Native Bible

Esther 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò ì tí ì tẹ́ mi lọ́rùn níwọ̀n ìgbà tí mo bá sì ń rí Mordekai ará a Júù náà tí ó ń jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ọba.”

Esther 5:13 in English

Esther 5:13 · Berean Standard Bible

Yet none of this satisfies me as long as I see Mordecai the Jew sitting at the king’s gate.”

Context

11Hamani gbéraga sí wọn nípa títóbi ọ̀rọ̀ rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ọ̀nà tí ọba ti bu ọlá fún un àti bí ó ṣe gbé e ga ju àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè tókù lọ. 12Hamani tún fi kún un pé, “Kì í ṣe èyí nìkan. Èmi nìkan ni ayaba Esteri pè láti sin ọba wá sí ibi àsè tí ó sè. Bákan náà, ó sì tún ti pè mí pẹ̀lú ọba ní ọ̀la. 13Ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò ì tí ì tẹ́ mi lọ́rùn níwọ̀n ìgbà tí mo bá sì ń rí Mordekai ará a Júù náà tí ó ń jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ọba.” 14Ìyàwó rẹ̀ Sereṣi àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “Ri igi kan, kí ó ga tó ìwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ bàtà márùn le láàdọ́rin, kí o sì sọ fún ọba ní òwúrọ̀ ọ̀la kí ó gbé Mordekai rọ̀ sórí i rẹ̀. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọba lọ sí ibi àsè pẹ̀lú ayọ̀.” Èrò yí dùn mọ́ Hamani nínú, ó sì ri igi náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.