Native Bible

Esther 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀.

Esther 3:12 in English

Esther 3:12 · Berean Standard Bible

On the thirteenth day of the first month, the royal scribes were summoned and the order was written exactly as Haman commanded the royal satraps, the governors of each province, and the officials of each people, in the script of each province and the language of every people. It was written in the name of King Xerxes and sealed with the royal signet ring.

Context

10Nítorí náà, ọba sì bọ́ òrùka èdìdì tí ó wà ní ìka rẹ̀, ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. 11Ọba sọ fún Hamani pé, “Pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.” 12Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀. 13A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko ọba pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari kí a sì kó àwọn ohun ìní wọn. 14Kí ẹ mú àdàkọ ìwé náà kí a tẹ̀ ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ó sì di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.