Esteri 2:4
Esther 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Faṣti.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e.
Esther 2:4 in English
Esther 2:4 · Berean Standard Bible
Then let the young woman who pleases the king become queen in place of Vashti.” This suggestion pleased the king, and he acted accordingly.
Context
2Nígbà náà ni ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a wá ọmọbìnrin arẹwà tí kò ì ti mọ ọkùnrin rí fún ọba. 3Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Susa. Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára. 4Nígbà náà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Faṣti.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e. 5Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mordekai ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi, ẹ̀yà Benjamini, 6ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jekoniah ọba Juda.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.