Esteri 10
Esther 10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ọba Ahaswerusi sì fi owó ọba lélẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ọba, dé erékùṣù òkun. 2Gbogbo ìṣe agbára àti títóbi rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìròyìn títóbi Mordekai ní èyí tí ọba ti gbé e ga, kò ha wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ọdọọdún ọba ti Media àti ti Persia? 3Mordekai ará Júù ni ó jẹ́ igbákejì ọba Ahaswerusi, ó tóbi láàrín àwọn Júù, ó sì jẹ́ ẹni iyì lọ́dọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, nítorí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ìre àwọn ènìyàn an rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ fún àlàáfíà gbogbo àwọn Júù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.