Esteri 1:7
Esther 1:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí.
Esther 1:7 in English
Esther 1:7 · Berean Standard Bible
Beverages were served in an array of goblets of gold, each with a different design, and the royal wine flowed freely, according to the king’s bounty.
Context
5Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba ṣe àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa. 6Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elése àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mabu. Àwọn ibùsùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mabu, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn. 7Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí. 8Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ. 9Ayaba Faṣti náà ṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ahaswerusi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.