Native Bible

Esther 1:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí ológun láti Persia àti Media, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

Esther 1:3 in English

Esther 1:3 · Berean Standard Bible

In the third year of his reign, Xerxes held a feast for all his officials and servants. The military leaders of Persia and Media were there, along with the nobles and princes of the provinces.

Context

1Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Ahaswerusi, tí ó jẹ ọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje (127) ìletò bẹ̀rẹ̀ láti India títí ó fi dé Etiopia. 2Ní àkókò ìgbà náà ọba Ahaswerusi ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Susa, 3ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí ológun láti Persia àti Media, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 4Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọláńlá rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko. 5Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba ṣe àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.