Native Bible

Esther 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena àti Memukani, àwọn ọlọ́lá méje ti Persia àti Media tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba.

Esther 1:14 in English

Esther 1:14 · Berean Standard Bible

His closest advisors were Carshena, Shethar, Admatha, Tarshish, Meres, Marsena, and Memucan, the seven princes of Persia and Media who had personal access to the king and ranked highest in the kingdom.

Context

12Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ. 13Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò, 14àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena àti Memukani, àwọn ọlọ́lá méje ti Persia àti Media tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba. 15Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Faṣti gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ahaswerusi tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.” 16Memukani sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Faṣti ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba Ahaswerusi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.