Esteri 1:10
Esther 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bista, Harbona, Bigta àti Abagta, Setari àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún Ahaswerusi.
Esther 1:10 in English
Esther 1:10 · Berean Standard Bible
On the seventh day, when the king’s heart was merry with wine, he ordered the seven eunuchs who served him—Mehuman, Biztha, Harbona, Bigtha, Abagtha, Zethar, and Carkas—
Context
8Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ. 9Ayaba Faṣti náà ṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ahaswerusi. 10Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bista, Harbona, Bigta àti Abagta, Setari àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún Ahaswerusi. 11Kí wọn mú ayaba Faṣti wá síwájú rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà. 12Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.