Native Bible

Ephesians 6:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àfikún, ẹ mú àpáta ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà.

Ephesians 6:16 in English

Ephesians 6:16 · Berean Standard Bible

In addition to all this, take up the shield of faith, with which you can extinguish all the flaming arrows of the evil one.

Context

14Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìyìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16Ní àfikún, ẹ mú àpáta ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 18Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.