Efesu 2:20
Ephesians 2:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé.
Ephesians 2:20 in English
Ephesians 2:20 · Berean Standard Bible
built on the foundation of the apostles and prophets, with Christ Jesus Himself as the cornerstone.
Context
18Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan. 19Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àjèjì mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jogún ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ará ilé Ọlọ́run; 20a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé. 21Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ ṣọ̀kan tí ó sì ń dàgbàsókè láti di tẹmpili mímọ́ kan nínú Olúwa. 22Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.