Efesu 2:13
Ephesians 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi.
Ephesians 2:13 in English
Ephesians 2:13 · Berean Standard Bible
But now in Christ Jesus you who once were far away have been brought near through the blood of Christ.
Context
11Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ Kèfèrí nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní “aláìkọlà” láti ọwọ́ àwọn tí ń pe ara wọn “akọlà” (èyí ti a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe sí ni ní ara). 12Ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kristi, ẹ jẹ́ àjèjì sí Israẹli, àti àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé. 13Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi. 14Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. 15Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.