Efesu 1:17
Ephesians 1:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i.
Ephesians 1:17 in English
Ephesians 1:17 · Berean Standard Bible
that the God of our Lord Jesus Christ, the glorious Father, may give you a spirit of wisdom and revelation in your knowledge of Him.
Context
15Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 16Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi. 17Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 18Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.