Native Bible

Ecclesiastes 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níwọ́n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá, ta ni ó le è sọ fún un ohun tí ó ń bọ̀?

Ecclesiastes 8:7 in English

Ecclesiastes 8:7 · Berean Standard Bible

Since no one knows what will happen, who can tell him what is to come?

Context

5Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan, àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é. 6Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe, ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀. 7Níwọ́n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá, ta ni ó le è sọ fún un ohun tí ó ń bọ̀? 8Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbà á dúró, nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀. Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀; bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà búburú kò le gba àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀. 9Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń múlò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kan wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tókù fún ìpalára rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.