Oniwaasu 8:13
Ecclesiastes 8:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run.
Ecclesiastes 8:13 in English
Ecclesiastes 8:13 · Berean Standard Bible
Yet because the wicked do not fear God, it will not go well with them, and their days will not lengthen like a shadow.
Context
11Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. 12Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀. 13Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run. 14Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òṣìkà àti ènìyàn búburú tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo sọ wí pé eléyìí gan an kò ní ìtumọ̀. 15Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnnú yóò bá a rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.