Native Bible

Ecclesiastes 8:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.

Ecclesiastes 8:10 in English

Ecclesiastes 8:10 · Berean Standard Bible

Then too, I saw the burial of the wicked who used to go in and out of the holy place, and they were praised * in the city where they had done so. This too is futile.

Context

8Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbà á dúró, nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀. Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀; bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà búburú kò le gba àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀. 9Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń múlò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kan wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tókù fún ìpalára rẹ̀. 10Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀. 11Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. 12Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.