Native Bible

Ecclesiastes 2:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú.

Ecclesiastes 2:23 in English

Ecclesiastes 2:23 · Berean Standard Bible

Indeed, all his days are filled with grief, and his task is sorrowful; even at night, his mind does not rest. This too is futile.

Context

21Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá. 22Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? 23Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú. 24Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run. 25Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.