Native Bible

Ecclesiastes 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé, “Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”? Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́, o ti wà ṣáájú tiwa.

Ecclesiastes 1:10 in English

Ecclesiastes 1:10 · Berean Standard Bible

Is there a case where one can say, “Look, this is new”? It has already existed in the ages before us.

Context

8Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá, ju èyí tí ẹnu le è sọ. Ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́. 9Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn òun ni a ó tún máa ṣe padà kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn. 10Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé, “Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”? Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́, o ti wà ṣáájú tiwa. 11Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú bẹ́ẹ̀ ni ìrántí kì yóò sí fún ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn. 12Èmi, Oniwaasu ti jẹ ọba lórí Israẹli ní Jerusalẹmu rí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.