Native Bible

Deuteronomy 9:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni Olúwa Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ jẹ́.

Deuteronomy 9:6 in English

Deuteronomy 9:6 · Berean Standard Bible

Understand, then, that it is not because of your righteousness that the LORD your God is giving you this good land to possess, for you are a stiff-necked people.

Context

4Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, “Torí òdodo mi ní Olúwa ṣe mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà.” Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Olúwa yóò ṣe lé wọn jáde níwájú u yín. 5Kì í ṣe nítorí òdodo yín, tàbí ìdúró ṣinṣin ni ẹ ó fi wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. 6Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni Olúwa Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ jẹ́. 7Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ̀yin ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní aginjù. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Ejibiti ni ẹ̀yin ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ̀yin fi dé ìhín yìí. 8Ní Horebu ẹ̀yin ti mú kí Olúwa bínú, títí dé bi pé ó fẹ́ run yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.