Native Bible

Deuteronomy 8:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.

Deuteronomy 8:18 in English

Deuteronomy 8:18 · Berean Standard Bible

But remember that it is the LORD your God who gives you the power to gain wealth, in order to confirm His covenant that He swore to your fathers even to this day.

Context

16Ó fún yín ní manna láti jẹ nínú aginjù, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun bá à le tẹ orí yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó bá à lè dára fún un yín. 17Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.” 18Ṣùgbọ́n ẹ rántí Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí. 19Bí ẹ bá wá gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn, tí ẹ sì sìn wọ́n, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, Mo kìlọ̀ fún un yín pé rírun ni ẹ̀yin yóò run. 20Bí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa parun níwájú u yín, bákan náà ni ẹ ó parun, torí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín lẹ́nu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.