Native Bible

Deuteronomy 8:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ kíyèsi i láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ bá à le yè, kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí Olúwa fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.

Deuteronomy 8:1 in English

Deuteronomy 8:1 · Berean Standard Bible

You must carefully follow every commandment I am giving you today, so that you may live and multiply, and enter and possess the land that the LORD swore to give your fathers.

Context

1Ẹ kíyèsi i láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ bá à le yè, kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí Olúwa fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. 2Ẹ rántí bí Olúwa Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín ṣọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí yín ba àti láti dán an yín wò kí ó ba à le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. 3Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi manna bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó ba à lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láààyè, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu Olúwa wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.