Native Bible

Deuteronomy 7:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

torí pé wọ́n yóò yí àwọn ọmọ rẹ padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú Olúwa yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì run yín kíákíá.

Deuteronomy 7:4 in English

Deuteronomy 7:4 · Berean Standard Bible

because they will turn your sons away from following Me to serve other gods. Then the anger of the LORD will burn against you, and He will swiftly destroy you.

Context

2nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì ti fi wọ́n lé ẹ lọ́wọ́, tí ìwọ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ìwọ kí ó sì pa wọ́n run pátápátá. Má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn. 3Ìwọ kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin rẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ, 4torí pé wọ́n yóò yí àwọn ọmọ rẹ padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú Olúwa yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì run yín kíákíá. 5Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn, ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Aṣerah wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná. 6Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, Olúwa Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrín gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.