Deuteronomi 7:21
Deuteronomy 7:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
Deuteronomy 7:21 in English
Deuteronomy 7:21 · Berean Standard Bible
Do not be terrified by them, for the LORD your God, who is among you, is a great and awesome God.
Context
19Ẹ sá à fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù. 20Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrín wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sá pamọ́ fún un yín, yóò fi ṣègbé. 21Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 22Olúwa Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò nígbà yín láààyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko igbó má ba à gbilẹ̀ sí i láàrín yín. 23Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.