Native Bible

Deuteronomy 7:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ náà, tí ìwọ yóò wọ̀ lọ láti gbà, tí ìwọ yóò sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kúrò níwájú rẹ. Àwọn ará Hiti, Girgaṣi, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi. Àwọn orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀jù ọ lọ,

Deuteronomy 7:1 in English

Deuteronomy 7:1 · Berean Standard Bible

When the LORD your God brings you into the land that you are entering to possess, and He drives out before you many nations—the Hittites, Girgashites, Amorites, Canaanites, Perizzites, Hivites, and Jebusites, seven nations larger and stronger than you—

Context

1Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ náà, tí ìwọ yóò wọ̀ lọ láti gbà, tí ìwọ yóò sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kúrò níwájú rẹ. Àwọn ará Hiti, Girgaṣi, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi. Àwọn orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀jù ọ lọ, 2nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì ti fi wọ́n lé ẹ lọ́wọ́, tí ìwọ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ìwọ kí ó sì pa wọ́n run pátápátá. Má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn. 3Ìwọ kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin rẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.