Deuteronomi 5:29
Deuteronomy 5:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé.
Deuteronomy 5:29 in English
Deuteronomy 5:29 · Berean Standard Bible
If only they had such a heart to fear Me and keep all My commandments always, so that it might be well with them and with their children forever.
Context
27Súnmọ́ tòsí ibẹ̀ kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò sọ, nígbà náà sọ ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wa sọ fún ọ fún wa. A ó sì fetísílẹ̀, a ó sì gbọ́rọ̀.” 28Olúwa ń gbọ́ nígbà tí ẹ̀yin ń bá mi sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ dára, 29ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé. 30“Lọ sọ fún wọn kí wọn padà sínú àgọ́ wọn. 31Ṣùgbọ́n ìwọ túbọ̀ dúró síbí pẹ̀lú mi, kí n bá à lè fún ọ ní àwọn àṣẹ tí o gbọdọ̀ fi kọ́ wọn láti máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún wọn láti ní.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.