Native Bible

Deuteronomy 5:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín.

Deuteronomy 5:12 in English

Deuteronomy 5:12 · Berean Standard Bible

Observe the Sabbath day by keeping it holy, as the LORD your God has commanded you.

Context

10Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́. 11Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi. 12Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín. 13Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ. 14Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti akọ màlúù rẹ, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, àti ohun ọ̀sìn rẹ kan, àti àlejò tí ń bẹ nínú ibodè rẹ; kí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin kí ó lè sinmi gẹ́gẹ́ bí ìwọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.