Native Bible

Deuteronomy 4:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní.

Deuteronomy 4:5 in English

Deuteronomy 4:5 · Berean Standard Bible

See, I have taught you statutes and ordinances just as the LORD my God has commanded me, so that you may follow them in the land that you are about to enter and possess.

Context

3Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Olúwa ṣe ní Baali-Peori. Olúwa Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Baali-Peori kúrò ní àárín yín. 4Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láààyè lónìí. 5Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní. 6Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.” 7Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkígbà tí a bá ń ké pè é?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.