Deuteronomi 4:46
Deuteronomy 4:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Beti-Peori ní ìlà-oòrùn Jordani; ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn Amori tí ó jẹ ọba Heṣboni tí Mose àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Ejibiti bọ̀.
Deuteronomy 4:46 in English
Deuteronomy 4:46 · Berean Standard Bible
while they were in the valley across the Jordan facing Beth-peor in the land of Sihon king of the Amorites, who lived in Heshbon and was defeated by Moses and the Israelites after they had come out of Egypt.
Context
44Èyí ni òfin tí Mose gbé kalẹ̀ fún àwọn ará Israẹli. 45Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀rí, àti ìlànà àti ìdájọ́ tí Mose fi lélẹ̀ fún ún àwọn ọmọ Israẹli, lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde kúrò ní Ejibiti. 46Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Beti-Peori ní ìlà-oòrùn Jordani; ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn Amori tí ó jẹ ọba Heṣboni tí Mose àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Ejibiti bọ̀. 47Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀, àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani àwọn ọba Amori méjèèjì tí ń bẹ ní ìlà-oòrùn Jordani. 48Ilẹ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri ní etí odò Arnoni dé orí òkè Sirioni (èyí ni Hermoni).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.