Deuteronomi 4:34
Deuteronomy 4:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnra rẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín?
Deuteronomy 4:34 in English
Deuteronomy 4:34 · Berean Standard Bible
Or has any god tried to take as his own a nation out of another nation—by trials, signs, wonders, and war, by a strong hand and an outstretched arm, and by great terrors—as the LORD your God did for you in Egypt, before your eyes?
Context
32Ẹ béèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ béèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkí báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí? 33Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè? 34Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnra rẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín? 35A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀. 36Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní ayé, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.