Native Bible

Deuteronomy 4:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá. Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí.

Deuteronomy 4:23 in English

Deuteronomy 4:23 · Berean Standard Bible

Be careful that you do not forget the covenant of the LORD your God that He made with you; do not make an idol for yourselves in the form of anything He has forbidden you.

Context

21Inú Olúwa ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jordani kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí Olúwa Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín. 22Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jordani kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdìkejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà. 23Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá. Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí. 24Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni. 25Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́, bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.