Native Bible

Deuteronomy 4:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.

Deuteronomy 4:2 in English

Deuteronomy 4:2 · Berean Standard Bible

You must not add to or subtract from what I command you, so that you may keep the commandments of the LORD your God that I am giving you.

Context

1Gbọ́ Israẹli, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín. 2Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́. 3Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Olúwa ṣe ní Baali-Peori. Olúwa Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Baali-Peori kúrò ní àárín yín. 4Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láààyè lónìí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.