Native Bible

Deuteronomy 4:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi,

Deuteronomy 4:15 in English

Deuteronomy 4:15 · Berean Standard Bible

So since you saw no form of any kind on the day the LORD spoke to you out of the fire at Horeb, be careful

Context

13Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì. 14Olúwa sì pàṣẹ fún mi nígbà náà láti kọ yín ní ìlànà àti ìdájọ, kí ẹ̀yin kí ó lè máa ṣe wọ́n ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ẹ̀yin ń lọ láti gbà á. 15Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi, 16kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin, 17tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò ní òfúrufú,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.