Native Bible

Deuteronomy 34:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

gúúsù àti gbogbo àfonífojì Jeriko, ìlú ọlọ́pẹ dé Soari.

Deuteronomy 34:3 in English

Deuteronomy 34:3 · Berean Standard Bible

the Negev, and the region from the Valley of Jericho (the City of Palms) all the way to Zoar.

Context

1Nígbà náà ni Mose gun òkè Nebo láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu sí orí Pisga tí ó dojúkọ Jeriko. Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gileadi dé Dani, 2gbogbo Naftali, ilẹ̀ Efraimu àti Manase, gbogbo ilẹ̀ Juda títí dé Òkun Ńlá, 3gúúsù àti gbogbo àfonífojì Jeriko, ìlú ọlọ́pẹ dé Soari. 4Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò dé bẹ̀.” 5Bẹ́ẹ̀ ni Mose ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Moabu, bí Olúwa ti wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.