Deuteronomi 32:49
Deuteronomy 32:49 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn.
Deuteronomy 32:49 in English
Deuteronomy 32:49 · Berean Standard Bible
“Go up into the Abarim Range to Mount Nebo, in the land of Moab across from Jericho, and view the land of Canaan, which I am giving to the Israelites as their own possession.
Context
47Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.” 48Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Mose pé, 49“Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn. 50Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀. 51Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.