Deuteronomi 31:15
Deuteronomy 31:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Olúwa farahàn níbi àgọ́ ní ọ̀wọ́ àwọsánmọ̀, àwọsánmọ̀ náà sì dúró sókè ẹnu-ọ̀nà àgọ́.
Deuteronomy 31:15 in English
Deuteronomy 31:15 · Berean Standard Bible
Then the LORD appeared at the tent in a pillar of cloud, and the cloud stood over the entrance to the tent.
Context
13Àwọn ọmọ wọn tí wọn kò mọ òfin yìí, gbọdọ̀ gbọ́ kí wọn sì kọ́ láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ níwọ̀n ìgbà tí o tí ń gbé ní ilẹ̀ tí ò ń kọjá la Jordani lọ láti ni.” 14Olúwa sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ ikú rẹ ti súnmọ́ etílé báyìí. Pe Joṣua kí ẹ sì fi ara yín hàn nínú àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti fi àṣẹ fún un.” Nígbà náà ni Mose àti Joṣua wá, wọ́n sì fi ara wọn hàn níbi àgọ́ àjọ. 15Nígbà náà ni Olúwa farahàn níbi àgọ́ ní ọ̀wọ́ àwọsánmọ̀, àwọsánmọ̀ náà sì dúró sókè ẹnu-ọ̀nà àgọ́. 16Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Ìwọ ń lọ sinmi pẹ̀lú àwọn baba à rẹ, àwọn wọ̀nyí yóò sì ṣe àgbèrè ara wọn sí ọlọ́run àjèjì ilẹ̀ tí wọn ń wọ̀ lọ láìpẹ́. Wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀ wọn yóò sì da májẹ̀mú tí mo bá wọn dá. 17Ní ọjọ́ náà ni èmi yóò bínú sí wọn èmi yóò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀; èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò fún wọn, wọn yóò sì parun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti ìṣòro yóò wá sórí wọn, àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ìpọ́njú wọ̀nyí kò wá sórí i wa nítorí Ọlọ́run wa kò sí pẹ̀lú u wa?’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.