Deuteronomi 30:9
Deuteronomy 30:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ. Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ.
Deuteronomy 30:9 in English
Deuteronomy 30:9 · Berean Standard Bible
So the LORD your God will make you abound in all the work of your hands and in the fruit of your womb, the offspring of your livestock, and the produce of your land. Indeed, the LORD will again delight in your goodness, as He delighted in that of your fathers,
Context
7Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú gbogbo ègún yín wá sórí àwọn ọ̀tá à rẹ tí wọ́n kórìíra àti tí wọ́n ṣe inúnibíni rẹ. 8Ìwọ yóò tún gbọ́rọ̀ sí Olúwa àti tẹ̀lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí. 9Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ. Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ. 10Bí o bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ. 11Nítorí àṣẹ yìí tí mo pa fún ọ lónìí, kò ṣòro jù fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò kọjá agbára rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.