Native Bible

Deuteronomy 30:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti fọ́n yín ká sí.

Deuteronomy 30:3 in English

Deuteronomy 30:3 · Berean Standard Bible

then He will restore you from captivity * and have compassion on you and gather you from all the nations to which the LORD your God has scattered you.

Context

1Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ síwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, 2àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí. 3Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti fọ́n yín ká sí. 4Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà. 5Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀. Olúwa yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ sí i ju àwọn baba yín lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.