Native Bible

Deuteronomy 3:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “Olúwa Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ní i. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín: ará Israẹli.

Deuteronomy 3:18 in English

Deuteronomy 3:18 · Berean Standard Bible

At that time I commanded you: “The LORD your God has given you this land to possess. All your men of valor are to cross over, armed for battle, ahead of your brothers, the Israelites.

Context

16ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Reubeni àti ọmọ Gadi ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gileadi lọ dé odò Arnoni (àárín odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jabbok. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ammoni. 17Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah pẹ̀lú, àti Jordani gẹ́gẹ́ bí òpin ilẹ̀ rẹ̀, láti Kinnereti lọ títí dé Òkun pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah, àní Òkun Iyọ̀, ní ìsàlẹ̀ àwọn orísun Pisga ní ìhà ìlà-oòrùn. 18Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “Olúwa Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ní i. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín: ará Israẹli. 19Àwọn ẹ̀yà a yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ohun ọ̀sìn in yín (mo mọ̀ pé ẹ ti ní ohun ọ̀sìn púpọ̀) lè dúró ní àwọn ìlú tí mo fi fún un yín, 20títí di ìgbà tí Olúwa yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jordani. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.