Native Bible

Deuteronomy 3:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn èyí ní a yípadà tí a sì kọrí sí ọ̀nà tí ó lọ sí Baṣani, Ogu ọba Baṣani àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ ṣígun wá pàdé wa ní Edrei.

Deuteronomy 3:1 in English

Deuteronomy 3:1 · Berean Standard Bible

Then we turned and went up the road to Bashan, and Og king of Bashan and his whole army came out to meet us in battle at Edrei.

Context

1Lẹ́yìn èyí ní a yípadà tí a sì kọrí sí ọ̀nà tí ó lọ sí Baṣani, Ogu ọba Baṣani àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ ṣígun wá pàdé wa ní Edrei. 2Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. Kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.” 3Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wa fi Ogu ọba Baṣani àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. A kọlù wọ́n títí kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.