Native Bible

Deuteronomy 29:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àjèjì tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi rẹ.

Deuteronomy 29:11 in English

Deuteronomy 29:11 · Berean Standard Bible

your children and wives, and the foreigners in your camps who cut your wood and draw your water—

Context

9Nítorí náà, ẹ pa májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n, kí ẹ̀yin kí ó lè máa rí ire nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe. 10Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ: àwọn olórí yín, àwọn ẹ̀yà yín, àwọn àgbàgbà yín àti àwọn ìjòyè yín, àní gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Israẹli, 11pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àjèjì tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi rẹ. 12O dúró níhìn-ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí Olúwa ń ṣe pẹ̀lú rẹ lónìí yìí àti tí òun dè pẹ̀lú ìbúra, 13láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.