Native Bible

Deuteronomy 28:62 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.

Deuteronomy 28:62 in English

Deuteronomy 28:62 · Berean Standard Bible

You who were as numerous as the stars in the sky will be left few in number, because you would not obey the voice of the LORD your God.

Context

60Olúwa yóò mú gbogbo ààrùn Ejibiti tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá padà bá ọ, wọn yóò sì lẹ̀ mọ́ ọ. 61Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ìwé òfin yìí wá sórí rẹ, títí ìwọ yóò fi run. 62Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. 63Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní. 64Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.