Deuteronomi 27:5
Deuteronomy 27:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn.
Deuteronomy 27:5 in English
Deuteronomy 27:5 · Berean Standard Bible
Moreover, you are to build there an altar to the LORD your God, an altar of stones. You must not use any iron tool on them.
Context
3Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ. 4Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun. 5Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn. 6Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. 7Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.