Deuteronomi 26:4
Deuteronomy 26:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Deuteronomy 26:4 in English
Deuteronomy 26:4 · Berean Standard Bible
Then the priest shall take the basket from your hands and place it before the altar of the LORD your God,
Context
2mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé. 3Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé, “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.” 4Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ. 5Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. 6Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.