Native Bible

Deuteronomy 26:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.

Deuteronomy 26:11 in English

Deuteronomy 26:11 · Berean Standard Bible

So you shall rejoice—you, the Levite, and the foreigner dwelling among you—in all the good things the LORD your God has given to you and your household.

Context

9Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; 10àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀. 11Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ. 12Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó. 13Nígbà náà ní kí o wí fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pàṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.