Native Bible

Deuteronomy 24:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún baba wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.

Deuteronomy 24:16 in English

Deuteronomy 24:16 · Berean Standard Bible

Fathers shall not be put to death for their children, nor children for their fathers; each is to die for his own sin.*

Context

14Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ tálákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Israẹli tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ. 15San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣálẹ́, nítorí ó jẹ́ tálákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè ké pe Olúwa sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀. 16Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún baba wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀. 17Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlekè opó bí ẹ̀rí. 18Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Ejibiti tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.