Deuteronomi 23:13
Deuteronomy 23:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ìwọ kí ó sì mú ìwalẹ̀ kan pẹ̀lú ohun ìjà rẹ; yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ yóò bá gbọnṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó, kí ìwọ kí ó mú ìwalẹ̀, kí ìwọ kí ó sì yípadà, kí o sì bo ohun tí ó jáde láara rẹ.
Deuteronomy 23:13 in English
Deuteronomy 23:13 · Berean Standard Bible
And you must have a digging tool in your equipment so that when you relieve yourself you can dig a hole and cover up your excrement.
Context
11Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́. 12Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára. 13Kí ìwọ kí ó sì mú ìwalẹ̀ kan pẹ̀lú ohun ìjà rẹ; yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ yóò bá gbọnṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó, kí ìwọ kí ó mú ìwalẹ̀, kí ìwọ kí ó sì yípadà, kí o sì bo ohun tí ó jáde láara rẹ. 14Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrín àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀tá à rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrín yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ yín. 15Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.