Deuteronomi 22:17
Deuteronomy 22:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúńdíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fi aṣọ hàn níwájú àwọn àgbàgbà ìlú,
Deuteronomy 22:17 in English
Deuteronomy 22:17 · Berean Standard Bible
And now he has accused her of shameful conduct, saying, ‘I discovered that your daughter was not a virgin.’ But here is the proof of her virginity.” And they shall spread out the cloth before the city elders.
Context
15Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé, ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ìlú ní ẹnu-bodè. 16Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀. 17Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúńdíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fi aṣọ hàn níwájú àwọn àgbàgbà ìlú, 18àwọn àgbàgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ ní yà. 19Wọn yóò sì gba ìtánràn ọgọ́rùn-ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúńdíá Israẹli. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.