Native Bible

Deuteronomy 21:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí òkú yóò mú ẹgbọrọ abo màlúù tí kò ì ṣiṣẹ́ rí àti tí kò sì fà nínú àjàgà rí,

Deuteronomy 21:3 in English

Deuteronomy 21:3 · Berean Standard Bible

Then the elders of the city nearest the victim shall take a heifer that has never been yoked or used for work,

Context

1Tí a bá rí ọkùnrin tí a pa, ní ìdùbúlẹ̀ ní pápá nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ láti jogún, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á, 2àwọn àgbàgbà yín yóò jáde lọ láti wọn jíjìnnà ibi òkú sí ìlú tí ó wà nítòsí. 3Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí òkú yóò mú ẹgbọrọ abo màlúù tí kò ì ṣiṣẹ́ rí àti tí kò sì fà nínú àjàgà rí, 4kí àwọn àgbàgbà ìlú náà kí wọn mú ẹgbọrọ abo màlúù náà sọ̀kalẹ̀ wá sí àfonífojì tí ó ní omi ṣíṣàn kan, tí a kò ro, tí a kò sì gbìn, kí wọn kí ó sì ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ màlúù náà níbẹ̀ ní àfonífojì náà. 5Àwọn àlùfáà, ọmọ Lefi yóò wá síwájú, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ Olúwa àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.