Deuteronomi 21:23
Deuteronomy 21:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
o kò gbọdọ̀ fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ sára igi ní gbogbo òru. Gbìyànjú láti sin ín ní ọjọ́ náà gan an, nítorí ẹni tí a bá gbé kọ́ sórí igi wà lábẹ́ ègún Ọlọ́run. Ìwọ kò gbọdọ̀ ba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún jẹ́.
Deuteronomy 21:23 in English
Deuteronomy 21:23 · Berean Standard Bible
you must not leave the body on the tree overnight, but you must be sure to bury him that day, because anyone who is hung on a tree is under God’s curse.* You must not defile the land that the LORD your God is giving you as an inheritance.
Context
21Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrín yín, gbogbo Israẹli yóò gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n. 22Bí ọkùnrin kan tí ó jẹ̀bi ẹ̀sùn bá ní láti kú tí ó sì kú, tí a sì gbé òkú rẹ̀ kọ́ sára igi, 23o kò gbọdọ̀ fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ sára igi ní gbogbo òru. Gbìyànjú láti sin ín ní ọjọ́ náà gan an, nítorí ẹni tí a bá gbé kọ́ sórí igi wà lábẹ́ ègún Ọlọ́run. Ìwọ kò gbọdọ̀ ba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún jẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.