Native Bible

Deuteronomy 2:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ammoni, ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ammoni fún un yín ní ìní. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọti ní ìní.”

Deuteronomy 2:19 in English

Deuteronomy 2:19 · Berean Standard Bible

But when you get close to the Ammonites, do not harass them or provoke them, for I will not give you any of the land of the Ammonites. I have given it to the descendants of Lot as their possession.”

Context

17Olúwa sọ fún mi pé, 18“Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbègbè Moabu kọjá ní Ari. 19Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ammoni, ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ammoni fún un yín ní ìní. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọti ní ìní.” 20(A ka ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ àwọn Refaimu, tí wọ́n ti gbé níbẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ará Ammoni ń pè wọ́n ní ará Samsummimu. 21Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tó lágbára, wọ́n sì pọ̀, wọ́n sì ga gogoro bí àwọn ará Anaki. Olúwa run wọn kúrò níwájú àwọn ará Ammoni, tí wọ́n lé wọn jáde tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.