Deuteronomi 18:9
Deuteronomy 18:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè náà tí ó wà níbẹ̀.
Deuteronomy 18:9 in English
Deuteronomy 18:9 · Berean Standard Bible
When you enter the land that the LORD your God is giving you, do not imitate the detestable ways of the nations there.
Context
7Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú Olúwa níbẹ̀. 8Wọn yóò ní ìpín kan láti jẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gba owó nípa títa ogún baba rẹ̀. 9Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè náà tí ó wà níbẹ̀. 10Má ṣe jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrín yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rú ẹbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́, 11tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwin gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókùúsọ̀rọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.